Kò ṣeé má gbọ̀ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́

Ariwo Daddy! Daddy!! Lọmọ mi n pa lẹyin ti ibọn ọlọpaa baa tan

Ọgbẹni Alade Ọdunayo, ti ọlọpaa yinbọn pa ọmọ rẹ niluu Ibadan lo sọ bẹẹ fun BBC

O ni lati ọdun meje sẹyin ni iya ọmọ naa ti kọ oun silẹ ti oun si n tọju wọn ṣaaju iṣẹlẹ ọhun

Ẹkunrẹrẹ ohun to sọ wa loju opo BBC Yoruba

______________________________

Ajijagbara fun ominira Yoruba Nation, Sunday Igboho ti sọ pe ijọba Naijiria ṣi n wa oun kiri titi di akoko yii

O ni bo tilẹ jẹ pe ọmọ Naijiria loun, iwe irinna orilẹede Germany loun fi n rinrinajo kaakiri agbaye

Igboho sọ pe ẹṣẹ oun ko ju pe oun sọrọ soke lodi si bi awọn darandaran kan ṣe n gbẹmi awọn agbẹ, ti wọn si n fipa ba obinrin lopọ nilẹ Yoruba

_______________________________

Ajọ to n ṣakoso ọgba ẹwọn ni Naijiria, (NCoS)

Ti kede pe oun ti ṣetan lati fun ẹnikẹni to ba le ṣeranwọ lati mu awọn ẹlẹwọn to ṣa kuro lọgba ẹwọn ilu Ilesha ni miliọnu marun naira

Ọjọ Iṣẹgun lawọn ẹlẹwọn naa salọ lẹyin ojo nla kan

Fun ẹkunrẹrẹ